1. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
2. Ènìyàn rere gba ojú rere lọ́dọ̀ Olúwaṣùgbọ́n Olúwa kórìíra alárekérekè ènìyàn.
3. A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburúṣùgbọ́n a kò le è fa Olódodo tu.
4. Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí ìgbà tí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
5. Ète àwọn Olódodo dáraṣùgbọ́n ìmúra ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.