Òwe 11:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parungbogbo ohun tó ń fojú sọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já sófo.

8. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibidípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.

9. Aláìmọ̀ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ Olódodo sá àsálà.

10. Nígbà tí Olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.

11. Nípaṣẹ̀ ìbùkún, Olódodo a gbé ìlú ga:ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.

Òwe 11