14. Nádì àti Ṣáfírónì,kálámúsì àti kínámónì,àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,òjíá àti álóépẹ̀lú irú wọn.
15. Ìwọ ni ọgbà oríṣun, kànga omi ìyè,ìṣàn omi láti Lẹ́bánónì wá.
16. Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwákí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúṣù!Fẹ́ lórí ọgbà mi,kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.