Orin Sólómónì 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní orí ìbùsùn mi ní òrumo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

2. Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

3. Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí miBí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4. Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọtítí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi

Orin Sólómónì 3