Nọ́ḿbà 29:32-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù.

33. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèṣè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

34. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

35. “ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpèjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

36. Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù.

37. Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́ àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

38. Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

Nọ́ḿbà 29