1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Míkà ará Mórésétì wá ní àkókò ìjọba Játamù, Áhásì, àti Heṣekáyà, àwọn ọba Júdà nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaríà àti Jérúsálẹ́mù.
2. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,fétísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,kí Olúwa alààyè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ̀ wá.
3. Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.
4. Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,àwọn àfonífojì yóò sì pín yà,bí idà níwájú iná,bí omi tí ó ń ṣàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
5. Nítorí ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù ni gbogbo èyí,àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì.Kí ni ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù?Ǹjẹ́ Samaríà ha kọ?Kí ni àwọn ibi gíga Júdà?Ǹjẹ́ Jérúsálẹ́mù ha kọ?
6. “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaríà bí òkítì lórí pápá,bí ibi ti à ń lò fún gbíngbin àjàrà.Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.