Mátíù 25:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má baà ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.

10. “Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àṣè ìgbéyàwó, lẹ̀yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.

11. “Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘olúwa, olúwa, sílẹ̀kùn fún wa.’

Mátíù 25