29. “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.
30. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kó pọ̀ ń fọ́nká.
31. Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a yóò dárí rẹ̀ ji ènìyàn, ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀-òdì-sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìdáríjì.
32. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dárí jì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí jì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.
33. “E ṣọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ ọ́n.
34. Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀.
35. Ẹni rere láti inú ìsúra rere ọkàn rẹ̀ ní i mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburu láti inú ìsúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá.
36. Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́.
37. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”
38. Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ àmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀”.
39. Ó sì dá wọn lóhùn wí pé “Ìran búburú àti ìran panságà ń béèrè àmì; ṣùgbọ́n kò sí àmí tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jónà wòlíì.