Máàkù 5:41-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ó gba a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Tàlítà kúùmì” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, díde dúró).

42. Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì ba wọn, ẹnú sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.

43. Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.

Máàkù 5