Lúùkù 8:27-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì.

28. Nígbà tí ó rí Jésù, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jésù, ìwọ ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”

29. (Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkúgbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì dá gbogbo ìdè náà, ẹmi ẹ̀sù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).

30. Jésù sì bí i pé, “Orúkọ rẹ?” Ó sì dáhùn pé,“Léjíónì,” nítorí ẹ̀mí ẹ̀ṣù púpọ̀ ni ó ti wọ̀ ọ́ lára lọ.

31. Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun.

32. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì yọ̀ǹda fún wọn.

33. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ: agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.

34. Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó sẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà.

35. Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jésù wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bá ẹsẹ̀ Jésù, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n.

36. Àwọn tí ó rí i ròyìn fún wọn bí ó ti ṣe mú ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù náà láradá.

37. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn láti ilẹ̀ Gádárà yíká bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn; nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ó sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojúomi, ó padà sẹ́yìn.

38. Ǹjẹ́ ọkùnrin náà tí ẹ̀mí ẹ̀sù jáde kúrò lára rẹ̀, bẹ̀ ẹ́ kí òun lè máa bá a gbé: ṣùgbọ́n Jésù rán an lọ, wí pé,

39. “Padà lọ sí ilé rẹ, kí o sì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún ọ bí ó ti pọ̀ tó.” Ó sì lọ, o sì ń ròyìn já gbogbo ìlú náà bí Jésù ti ṣe ohun ńlá fún òun tó.

40. Ó sì ṣe, nígbà tí Jésù padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.

41. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jáírù, ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bá ẹṣẹ̀ Jésù, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun:

42. Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ó ń kú lọ.Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ń há a ní àyè.

43. Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, (tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn), tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un lára dá,

Lúùkù 8