Lúùkù 4:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónì-ín ìwé-Mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”

22. Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Jósẹ́fù kọ́ yìí?”

23. Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”

Lúùkù 4