1. Jésù sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jọ́dánì wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù;
2. Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ Èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
3. Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”