55. Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrin gbọ̀ngàn, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Pétérù jokòó láàrin wọn.
56. Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”
57. Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”
58. Kò pẹ́ lẹ̀yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ọkùnrin yìí, Èmi kọ́.”
59. Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Gálílì ní í ṣe.”
60. Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ!
61. Olúwa sì yípadà, ó wo Pétérù. Pétérù sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.”
62. Pétérù sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
63. Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jésù, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú.
64. Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?”
65. Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí I, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.
66. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọ pọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé,
67. “Bí ìwọ́ bá jẹ́ Kírísítì náà? Sọ fún wa!”Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́;
68. Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ).
69. Ṣùgbọ́n láti ìsinsinyìí lọ ni ọmọ-ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”
70. Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”
71. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ Àwa tìkarawa sáà ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”