Lúùkù 2:49-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”

50. Ọ̀rọ̀ tí sọ kò sì yé wọn.

51. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Násárétì, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.

52. Jésù sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.

Lúùkù 2