Lúùkù 2:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.

19. Ṣùgbọ́n Màríà pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.

20. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.

21. Nígbà tí ijọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ańgẹ́lì náà wá kí á tó lóyún rẹ̀ nínú.

22. Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Màríà sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, Josefu àti Màríà gbé Jésù wá sí Jerúsálémù láti fi í fún Olúwa;

23. (Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),

24. àti láti rúbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “àdàbà méjì tàbí ẹyẹlẹ́ méjì.”

25. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà ní Jerúsálémù, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣíméónì; ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Ísírẹ́lì: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.

Lúùkù 2