Lúùkù 19:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mínà mẹ́wàá.’

26. “Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fifún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.

27. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhínyìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”

28. Nígbà tí ó sì ti wí ǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ ṣíwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálémù.

Lúùkù 19