Lúùkù 15:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́sẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́!

22. “Ṣùgbọ́n Baba náà wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀:

23. Ẹ sì mú ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á; kí a máa ṣe àríyá:

24. Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í se àríyá.

25. “Ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ èyí ẹ̀gbọ́n ti wà ní oko: bí ó sì ti ń bọ̀, tí ó súnmọ́ etí ilé, ó gbọ́ orin òun ijó.

26. Ó sì pe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn, ó béèrè, kíni a mọ nǹkan wọ̀nyí sí?

27. Ó sì wí fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa, nítorí tí ó rí i padà ní àlààáfíà àti ní ìlera.’

28. “Ó sì bínú, ó sì kọ̀ láti wọlé; bàbá rẹ̀ sì jáde, ó sì wá í sìpẹ̀ fún un.

29. Ó sì dáhùn ó wí fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wòó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí: ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá:

30. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà ru ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ìwọ sì ti pa ẹgbọ̀rọ̀ màlúù àbọ́pa fún un.’

31. “Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni.

32. Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”

Lúùkù 15