Lúùkù 13:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò níbùso, kì í sì í fà á lọ mumi lí ọjọ́ ìsinmi.

16. Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í se ọmọbìnrin Ábúráhámù sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí sàtánì ti dè, sáà wò ó láti ọdún májìdínlógún yìí wá?”

17. Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ògo gbogbo tí ó ṣe láti ọwọ́ rẹ̀ wá.

18. Ó sì wí pé, “Kíni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kíni èmi ó sì fi wé?

19. Ó dàbí hóró músítádì, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”

20. Ó sì tún wí pé, “Kíli èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé?

21. Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”

22. Ó sì ń la àárin ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọrin, ó sì ń rìn lọ sí ìhà Jerúsálémù.

23. Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha ni àwọn tí a ó gbàlà?Ó sì wí fún wọn pé,

24. “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.

25. Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fù ú, tí ó bá sí ìlẹ̀kùn ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’

26. “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú.’

27. “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

28. “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.

Lúùkù 13