4. “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.
5. Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpádì: lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.
6. Ológoṣẹ́ márùn ún sáà ni a ń tà lówó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?
7. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológóṣẹ́ púpọ̀ lọ.