Léfítíkù 26:44-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀ta wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kóríra wọn pátapáta: èyi tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Ọlọ́run wọn

45. Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú babańlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì lójú gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”

46. Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mósè ní orí òkè Sínáì láàrin òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Léfítíkù 26