Léfítíkù 15:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

2. Ẹ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀: kí ẹ wí fún wọn pé: Bí ìṣunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara: ìṣunjáde náà jẹ́ àìmọ́.

3. Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìṣunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́.

4. “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìṣunjáde náà bá sùn di àìmọ́.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá joko lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀: kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

7. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìṣunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

8. “ ‘Bí ẹni tí ó ní ìṣunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀: yóò sì wà nípò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

Léfítíkù 15