Jóòbù 11:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ,ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti ṣàn kọjá lọ.

17. Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísisinyìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.

18. Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.

19. Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,àní ènìyàn yóò máa wá ojú rere rẹ.

20. Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”

Jóòbù 11