15. Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láì ní àbàwọ́n,àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,
16. Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ,ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti ṣàn kọjá lọ.
17. Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísisinyìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18. Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19. Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,àní ènìyàn yóò máa wá ojú rere rẹ.
20. Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”