Jòhánù 7:13-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.

14. Nígbà tí àjọ dé àárin; Jésù gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ó sì ń kọ́ni.

15. Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

16. Jésù dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi.

17. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bíí bá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi.

18. Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòótọ́, kò sì sí àìsòdodo nínú rẹ̀.

19. Mósè kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

20. Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èsù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

21. Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ àmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín.

22. Síbẹ̀, nítorí pé Mósè fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ mósè bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi.

23. Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mósè, ẹ ha ti ṣe ń bínú sími, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ṣáṣá ní ọjọ́ ìsinmi?

24. Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa se ìdájọ́ òdodo.”

25. Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jérúsálẹ́mù wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí?

26. Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nkankan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, Èyí ni Kírísítì náà?

27. Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kírísítì bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

28. Nígbà náà ni Jésù kígbe ní Tẹ́mpìlì bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀.

29. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

30. Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà àtimú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.

Jòhánù 7