Jòhánù 6:9-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ọmọdékùnrin kan ńbẹ níhínyìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùnún àti ẹja kékèké méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

10. Jésù sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Kóríkó púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye.

11. Jésù sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọn bí wọ́n ti ń fẹ́.

12. Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.”

13. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.

14. Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́-àmì tí Jésù ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

15. Nígbà tí Jésù sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

16. Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun.

17. Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá òkun lọ sí Kápénámù. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jésù kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn.

18. Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúfù líle tí ńfẹ́.

19. Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jésù ń rìn lórí òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n.

20. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”

21. Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkannáà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n gbé ń lọ.

22. Ní ijọ́ kéjì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní apákejì òkun ríi pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jésù kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ.

23. Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberíà wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́;

24. Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jésù tàbí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kápánámù, wọ́n ń wá Jésù.

25. Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apákejì òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rábì, nígbà wo ni ìwọ wá síhín yìí?”

26. Jésù dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́-àmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà.

27. Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ńṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí ọmọ-ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”

28. Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Kín ni àwa ó ha ṣe, kí a lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run?”

29. Jésù dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni iṣe Ọlọ́run pé, kí ẹ̀yin gba ẹni tí ó rán an gbọ́.”

Jòhánù 6