1. Àwọn Farisí sì gbọ́ pé, Jésù ni, ó sì n ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ ẹyìn púpọ̀ ju Jóhánù lọ,
2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù tìkararẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmibí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀,
3. Nígbà tí Olúwa mọ nípa èyí, Ó fi Jùdéà sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Gálílì lẹ́ẹ̀kan si.
4. Òun sì ní láti kọjá láàárin Samaríà.
5. Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaríà kan, tí a ń pè ní Síkárì, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jákọ́bù ti fi fún Jóṣéfù, ọmọ rẹ̀.
6. Kànga Jákọ́bù sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jésù nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jòkó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
7. Obìrin kan, ará Samaríà sì wá láti fà omi: Jésù wí fún un pé fún mi mu.
8. (Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra ońjẹ.)
9. Obìnrin ará Samáríà náà sọ fún un pé, “Júù ni ẹ́ obìnrin ará Samáríà ni èmi. Eéti rí tí ìwọ ń bèèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaríà ṣe pọ̀.)