Jòhánù 2:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàsípàrọ̀ owó ní tẹ́ḿpìlì wọ́n jòko:

15. Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó sì bi tábìlì wọn ṣubú.

16. Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

17. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

18. Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ lè fi hàn wá, tí ìwọ fi ń se nǹkan wọ̀nyí?”

Jòhánù 2