11. Nítorí náà Jésù wí fún Pétérù pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ: ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”
12. Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀sọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jésù, wọ́n sì dè é.
13. Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Ánnà; nítorí òun ni àna Káyáfà, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà.
14. Káyáfà sáà ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfàní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.
15. Símónì Pétérù sì ń tọ Jésù lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jésù wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.
16. Ṣùgbọ́n Pétérù dúró ní ẹnu ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mímọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùsọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé.
17. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà wí fún Pétérù pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”Ó wí pé, “Èmi kọ́.”
18. Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn alaṣẹ́ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Pétérù sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.
19. Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jésù léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
20. Jésù dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù, àti ní Tẹ́ḿpìlì níbi tí gbogbo àwọn Júù ń pé jọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.
21. Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”