Jòhánù 11:7-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Jùdíà.”

8. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rábì, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”

9. Jésù dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.

10. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”

11. Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lásárù ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”

12. Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá se pé ó sùn, yóò sàn.”

13. Ṣùgbọ́n Jésù ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.

14. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú,

15. Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

16. “Nítorí náà Tómásì, ẹni tí à ń pè ní Dídímù, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”

17. Nítorí náà nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ijọ́ mẹ́rin ná,

18. Ǹjẹ́ Bétanì sún mọ́ Jérúsálẹ́mù tó ibùsọ Mẹ́ẹ̀dógún:

19. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Màta àti Màríà láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.

20. Nítorí náà, nígbà tí Màta gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé.

21. Nígbà náà, ni Màta wí fún Jésù pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.

22. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

23. Jésù wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

Jòhánù 11