Jòhánù 1:27-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”

28. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bétanì ní òdì kejì odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣe ìtẹ̀bọmi.

29. Ní ọjọ́ kejì Jòhánù rí Jésù tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!

30. Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’

31. Èmi gan-an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Ísírẹ́lì.”

32. Nígbà náà ni Jòhánù jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e.

33. Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitíìsì sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì.’

34. Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”

35. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jòhánù dúró, pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

36. Nígbà tí ó sì rí Jésù bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”

Jòhánù 1