Jóẹ́lì 2:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,yóò sì káànú fún ènìyàn rẹ̀.

19. Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn:“Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé,Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun,àti òróró síi yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn:èmi kì yóò si fí yín ṣe ẹ̀gan mọ́ láàrin àwọn aláìkọlà.

20. “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà oòrùn,àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀ oòrùn òkun.Oòrùn rẹ̀ yóò sì gòkè,òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.

21. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá,

22. Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,nítorí pápá-oko ihà ń rú,nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́àti àjàrà ń so èso ipá wọn.

23. Ǹjẹ́ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Ṣíónì,ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

Jóẹ́lì 2