1. Ẹ fun ìpè ní Ṣíónì,ẹ sì fún ìpè ìdágàrì ní òkè mímọ́ mi.Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì,nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá,nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.
2. Ọjọ́ òkùnkùn àti òkùdù,ọjọ́ ìkùùkù àti òkùnkùn biribiri,bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá:àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé,ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí,bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran.
3. Iná ń jó níwájú wọ́n;ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn:ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Édẹ́nì níwájú wọn,àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù;nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.