Jeremáyà 52:28-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.Ní ọdún keje ẹgbẹ̀dógún ó lé mẹ́talélógún ará Júdà.

29. Ní ọdún kejìdínlógún Nebakadinésárìo kó ẹgbẹ̀rún ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n láti Jérúsálẹ́mù.

30. Ní ọdún kẹtàlélógún ènìyànJúù tí Nebukadinésárì kó lọ sí ilẹ̀ àjòjì jẹ́ márùn ún.Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún.

31. Ní ọdún kẹtàdín lógójì ti Jéhóáíkímù Ọba Júdà ni Efili-merodaki di Ọba Bábílónì. Ó tú Jéhóáíkímù Ọba Júdà sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kéjìlá.

32. Ó ń sọ̀rọ̀ rere sí i, ó sì fún un ní ìjókòó ìgbéga, èyí tí ó ju ti àwọn Ọba yóòkù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì.

33. Nítorí náà, Jéhóáíkímù bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n rẹ̀ ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ fún ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀: Ó sì ń jẹun lórí àga Ọba.

34. Ní ojoojúmọ́ ni Ọba Bábílónì ń fún Jéhóáíkímù ní ìpín tirẹ̀ títí ọjọ́ ayé rẹ̀ tí ó fi kú.

Jeremáyà 52