9. Nítorí pé èmi yóò ru,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Bábílónì àwọn orílẹ̀ èdèńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀;Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóòdàbí ọfà àwọn akọni alákíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo
10. A ó dààmú Bábílónì, gbogboàwọn tó dààmú rẹ yóò sì múìfẹ́ wọn sẹ,”ni Olúwa wí.
11. “Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìnfi ayọ̀ fò bí ẹgbọ̀rọ̀ màlúù sí koríko tútù,ẹsì ń yan bí akọ-ẹsin.
12. Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọyóò sì gba ìtìjú.Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀ èdè,ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ihà tí kò lọ́ràá.
13. Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóòfi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.
14. “Dúró sí àyè rẹ ìwọ Bábílónìàti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ta ọfà náà.Ẹ ta ọfà náà síi, nítorí ó ti sẹ̀ sí Olúwa.
15. Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà!Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,gbẹ̀san lára rẹ̀.Ṣe síi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmìíràn.