Jeremáyà 50:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”ni Olúwa wí,“Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ wá,àwọn, àti àwọn ọmọ Júdà,wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́ri Olúwa Ọlọ́run wọn

5. Wọn ó máa bèèrè ọ̀nà Síhónì, oju wọnyóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí adarapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayé-rayé,tí a kì yóò gbàgbé.

6. “Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà,wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkèwọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.

7. Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹàwọn ọ̀ta wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀binítorí pé wọ́n ti sẹ̀ sí Olúwa ibùgbéòdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

Jeremáyà 50