20. “Ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tó lẹ́wà ní Éjíbítìṣùgbọ́n eṣinṣintí yóò le ń bọ̀ láti àríwá.
21. Àwọn jagunjagun rẹ̀dàbí àbọ́pa màlúù.Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,wọn ó sì jùmọ̀ sá,wọn kò ní le dúró,Nítorí tí ọjọ́ ibi ńbọ̀ lórí wọnàsìkò láti jẹ wọ́n níyà.
22. Éjíbítì yóò pòṣé bí ejò tí ń sábí ọmọ ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.
23. Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”ni Olúwa wí,“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,nítorí pé wọ́n pọ̀ ju elẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.
24. A ó dójú ti ọmọbìnrin Éjíbítì,a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”
25. Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: “Èmi ṣetán láti fi ìyà jẹ Ámónì, òrìṣà Tíbísì, Fáráò Éjíbítì àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti àwọn Ọba rẹ̀ àti àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Fáráò.
26. Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Éjíbítì yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.