Jeremáyà 46:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá nípa:Àwọn orílẹ̀ èdè:

2. Nípa Éjíbítì,Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò Ọba Éjíbítì ẹni tí a borí rẹ̀ ní Káṣímísì, ní odò Ẹ́fúrétà láti ọwọ́ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ní ọdún kẹrin Jéhóáíkímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà:

3. “Pèsè ọ̀kọ̀ rẹ sílẹ̀, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí o sì yan lọ síta fún ogun!

4. Di ẹṣin ní gàárì,kí ẹ sì gùn ún.Ẹ dúró lẹ́sẹsẹpẹ́lú àsíborí yín!Ẹ dán ọ̀kọ̀ wò,kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

5. Kí ni nǹkan tí mo tún rí?Wọ́n bẹ̀rù,wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.Wọ́n sá,wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”ni Olúwa wí.

6. “Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.Ní Gúṣù ní ibi odò Ẹ́fúrétàwọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

7. “Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Náílì,tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n ọn nì?

8. Éjíbítì dìde bí odò náà,bí omi odò tí ń ru.Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’Èmi yóò pa orílẹ̀ èdè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.

9. Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,ẹ̀yin ọkùnrin Kúṣì àti Pútì tí ń gbé ọ̀kọ̀;àti ẹ̀yin ọkùnrin Lìdíà tí ń fa ọrun.

Jeremáyà 46