10. Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jérúsálẹ́mù jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o fẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”
11. Nígbà náà ni a ó sọ fún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.
12. Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”
13. Wò ó! O ń bò bí ìkuukùukẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líleẸ̀ṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọÈgbé ni fún wa àwa parun.
14. Ìwọ Jérúsálẹ́mù, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yèYóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?
15. Ohùn kan sì ń kéde ní DánìÓ ń kókìkí ìparun láti orí òkè Éfúráímù wá.
16. “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀ èdè,kéde rẹ̀ fún Jérúsálẹ́mù pé:‘Ọmọ ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jínjìn wáWọ́n sì ń kígbe ogun láti dojú kọ ìlú Júdà.