3. Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì; tí yóò sì kó wa nígbékùn.’ ”
4. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún Ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tó kù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ire fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”
5. Sedekáyà Ọba sì wí pé, “Ó wà lọ́wọ́ yín. Ọba kò lè ṣe ohunkóhunm láti ta kò yín.”
6. Wọ́n gbé Jeremáyà sọ sínú àmù Málíkíà ọmọ Ọbakùnrin tó wà ní àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, wọ́n ju Jeremáyà sínú àmù pẹ̀lú okùn; kò sì sí omi níbẹ̀ àyàfi ẹrọ̀fọ̀ nìkan, Jeremáyà sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀.
7. Ṣùgbọ́n, Ebedimélékì, ará Kúṣì ìjòyè nínú ààfin Ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú àmù. Nígbà tí Ọba jókòó lẹ́nubodè Bẹ́ńjámínì.
8. Ebedimélékì jáde kúrò láàfin ó sì sọ fún un pé,
9. “Olúwa mi Ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú àmù níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”