Jeremáyà 36:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsàn-án, Ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná àrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀.

23. Nígbà tí Jéhúdù ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, Ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé náà fi jóná tán.

24. Síbẹ̀, Ọba àti gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá.

25. Elinátanì, Déláyà àti Jemaríà sì bẹ Ọba kí ó má ṣe fi ìwé náà jóná, ṣùgbọ́n Ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn.

Jeremáyà 36