Jeremáyà 26:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.

4. Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé síwájú yín.

5. Àti tí ẹ kò bá fetísí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò fetí sílẹ̀.

6. Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé.’ ”

Jeremáyà 26