Jeremáyà 25:27-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. “Nígbà náà, sọ fún wọn: Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Mu, kí o sì mu amuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárin yín.

28. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba aago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!

29. Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀ èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò há a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’

30. “Nísinsinyìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:“ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá,yóò sì bú àrá kíkankíkan sí ilẹ̀ náà.Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí

31. Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé,nítorí pé Olúwa yóò mú ìjà wá sí oríàwọn orílẹ̀ èdè náà,yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn,yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ”ni Olúwa wí.

32. Èyí ni ohun tí Olúwa ọmọ ogun wí:“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn;Ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”

Jeremáyà 25