Jeremáyà 2:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Wọn sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi,’àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọojú sí mi ṣíbẹ̀ nígbà tí wọ́nbá wà nínú ìṣòro, wọn yóòwí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’

28. Níbo wá ni àwọn Ọlọ́run (kékeré) tíẹ ṣe fúnra yín há a wà?Jẹ́ kí wọn wá kí wọn sìgbà yín nígbà tí ẹ báwà nínú ìṣòro! Nítorí péẹ̀yin ní àwọn Ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́bí ẹ ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Júdà.

29. “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”ni Olúwa wí.

30. “Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọnènìyàn yín, wọn kò sì gbaìbáwí, idà yín ti pa àwọnwòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bíkìnnìún tí ń bú ramúramù.

31. “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ Olúwa:“Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùnkí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣesọ wí pé, ‘A ní àǹfààní látimáa rìn kiri? A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́?’

Jeremáyà 2