1. Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbààgbà ọkùnrin àti wòlíì.
2. Hó sí àfonífojì Bẹni Hínínónì, nítòsí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pótísẹ́dì níbẹ̀ sì ni kí o kéde ọ̀rọ̀ tí mo bá ọ sọ.
3. Kí o sì wí pé ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin Ọba àwọn Júdà àti ẹ̀yin ará Jérúsálẹ́mù. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya.
4. Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjòjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí Ọba Júdà kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.
5. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Báálì láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sí Báálì. Nǹkan ni èmi kò pa láṣẹ tàbí dárúkọ tí kò sì wá láti inú ọkàn mi.
6. Nítorí náà sọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn tí a kì yóò pe ibí ní Tófẹ́tì tàbí ọmọ Hininómù, ṣùgbọ́n Àfonífojì ìpakúpa.