Jẹ́nẹ́sísì 9:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run sì súre fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún aye.

2. Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

3. Gbogbo ohun tó wà láàyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún-ún yín bí mo ṣe fi ewéko fún un yín, náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

4. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 9