Jẹ́nẹ́sísì 5:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Àpapọ̀ ọdún Ṣẹ́tì sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.

9. Nígbà tí Énọ́sì di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kénánì.

10. Lẹ́yìn tí ó bí Kénánì, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-lé-mẹ́ẹ̀dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.

11. Àpapọ̀ ọdún Énọ́sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.

12. Nígbà tí Kénánì di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Máhálálélì:

Jẹ́nẹ́sísì 5