Jẹ́nẹ́sísì 46:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí ni Ísírẹ́lì mú ìrìn-àjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Báá-Ṣébà, ó rúbọ sí Ọlọ́run Ísáákì baba rẹ̀.

2. Ọlọ́run sì bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ ní ojú ìrán ní òru pé, “Jákọ́bù! Jákọ́bù!”Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

3. Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá níbẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 46