Jẹ́nẹ́sísì 45:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Wọn wí fún un pé, “Jósẹ́fù sì wà láàyè! Kódà òun ni alákòóṣo ilẹ̀ Éjíbítì” Ẹnu ya Jákọ́bù, kò sì gbà wọ́n gbọ́

27. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jákọ́bù, baba wọn ṣọ.

28. Ísírẹ́lì sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Jósẹ́fù ọmọ mi wà láàyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”

Jẹ́nẹ́sísì 45