19. “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí: Ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Éjíbítì fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá.
20. Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun-ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Éjíbítì yóò jẹ́ tiyín.’ ”
21. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí. Jósẹ́fù fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Fáráò ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìn-àjò wọn pẹ́lú.
22. Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún ẹyọ owó (300) idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn ún.
23. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Éjíbítì àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ.
24. Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!”
25. Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ọ̀dọ̀ Jákọ́bù baba wọn ní ilẹ̀ Kénánì.