Jẹ́nẹ́sísì 44:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’

20. A sì dáhùn pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn an rẹ̀.’

21. “Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu-un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’

22. A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán-an wò baba rẹ̀ yóò kú.’

Jẹ́nẹ́sísì 44